30
Ìmúpadà sípò Israẹli
1 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé: 2 “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan. 3 Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”
4 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda: 5 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́
láìṣe igbe àlàáfíà.
6 Béèrè kí o sì rí.
Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?
Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin
tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,
tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?
7 Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!
Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,
Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu
ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.
8 “ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé,
‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn,
Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù.
Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́.
9 Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn
àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn,
ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.
10 “ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’
ni Olúwa wí.
‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá,
àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn.
Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà,
kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.
11 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’
ni Olúwa wí.
‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká,
síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá.
Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan;
Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’
12 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn,
bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.
13 Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín,
kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín,
a kò sì mú yín láradá.
14 Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ,
wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú.
Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ,
mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà,
nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀,
ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà.
15 Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín,
ìrora yín èyí tí kò ní oògùn?
Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga
ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín.
16 “ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,
àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì;
gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.
17 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,
èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí,
‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri,
Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’
18 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà,
èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀;
ìlú náà yóò sì di títúnṣe
tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.
19 Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti
ìyìn yóò sì ti máa jáde.
Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,
wọn kì yóò sì dínkù ní iye,
Èmi yóò fi ọlá fún wọn,
wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.
20 Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì
níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí.
Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára,
ni èmi yóò fì ìyà jẹ.
21 Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn,
ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn.
Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi,
nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’
ni Olúwa wí.
22 ‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi,
èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’ ”
23 Wò ó, ìbínú Olúwa yóò tú jáde,
ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.
24 Ìbínú ńlá Olúwa kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn
àwọn ìkà títí yóò fi mú
èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.
Ní àìpẹ́ ọjọ́,
òye rẹ̀ yóò yé e yín.