6
Ìdáhùn Jobu
Jobu sì dáhùn ó si wí pé,
“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n,
kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òsùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ,
nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé.
Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,
oró èyí tí ọkàn mi mú;
ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.
Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,
tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?
A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,
tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?
Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,
òun ni ó dàbí oúnjẹ tí ó mú mi ṣàárẹ̀.
 
“Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;
àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.
Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run,
tí òun ìbá jẹ́ ṣíwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.
10 Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,
àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:
nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.
 
11 “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?
Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?
12 Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí?
Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?
13 Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:
ọgbọ́n kò ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?
 
14 “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,
kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?
15 Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé
bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.
16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì,
àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.
17 Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,
nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.
18 Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn,
wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.
19 Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi,
àwọn oníṣòwò Ṣeba ń dúró dè wọ́n ní ìrètí.
20 Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e;
wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú.
21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;
ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.
22 Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,
tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?
23 Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,
tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’?
 
24 “Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́
kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà.
25 Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó
ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí?
26 Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe
àti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀.
27 Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,
ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.
 
28 “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.
Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé,
ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.
29 Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;
àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.
30 Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi?
Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?