Ìwé Juda
1
Juda, ìránṣẹ́ Jesu Kristi àti arákùnrin Jakọbu,
 
Sí àwọn tí a pè, olùfẹ́ nínú Ọlọ́run Baba, tí a pamọ́ fún Jesu Kristi:
 
Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
 
Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. 2Pt 2.1-18.Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọ́n ń yọ́ wọlé, àwọn ẹni tí a ti yàn láti ìgbà àtijọ́ sí ẹ̀bi yìí, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń sẹ́ Olúwa wa kan ṣoṣo náà, àní, Jesu Kristi Olúwa.
Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Ejibiti wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́. Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì. Gẹ 19.Àní bí Sodomu àti Gomorra, àti àwọn ìlú agbègbè wọn, ti fi ara wọn fún àgbèrè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun.
Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjòyè, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búburú sí àwọn ọlọ́lá. Sk 3.2.Ṣùgbọ́n Mikaeli, olórí àwọn angẹli, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítorí òkú Mose, kò sọ ọ̀rọ̀-òdì sí i; ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.” 10 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀-òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa èrò ara ni, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.
11  Gẹ 4.3-8; Nu 22.24; 16.Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora.
12 Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àsè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùṣọ́-àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọ́n tú tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 13 Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi Òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde; alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé.
14  Gẹ 5.18,21-24.Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Enoku, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Adamu, sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn pé, “Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́, 15 láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i.” 16 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nípa ara wọn, wọ́n sì ń ṣátá àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn.
Ìpè fún ìdúró ṣinṣin
17 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ṣáájú láti ọwọ́ àwọn aposteli Olúwa wa Jesu Kristi. 18  2Pt 3.3.Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.” 19 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni ti ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.
20 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́. 21 Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń retí àánú Olúwa wa Jesu Kristi tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun.
22 Ẹ máa ṣàánú fún àwọn tí ń ṣe iyèméjì. 23  Sk 3.3-4.Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná; kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èérí.
 
Orin ìyìn sí Ọlọ́run
24 Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọ̀sẹ̀, tí o sì lè mú yín wá síwájú ògo rẹ̀ láìlábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́— 25 tí Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọláńlá, ìjọba àti agbára, nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, kí gbogbo ayé tó wà, nísinsin yìí àti títí láéláé! Àmín.

1:4 2Pt 2.1-18.

1:7 Gẹ 19.

1:9 Sk 3.2.

1:11 Gẹ 4.3-8; Nu 22.24; 16.

1:14 Gẹ 5.18,21-24.

1:18 2Pt 3.3.

1:23 Sk 3.3-4.