Ìwé Ìyìnrere Marku
1
Johanu onítẹ̀bọmi tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀
Ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.
Mt 3.1-12; Lk 3.2-16; Jh 1.6,15,19-28.Ml 3.1; Mt 11.10; Lk 7.27.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé,
“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ,
Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
Isa 40.3.“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”
Ap 13.24.Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”
Ìtẹ̀bọmi àti ìdánwò Jesu
Mt 3.13-17; Lk 3.21-22; Jh 1.29-34.Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. 11 Sm 2.7. Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
12 Mt 4.1-11; Lk 4.1-13.Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, 13 Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.
Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
14 Mt 4.12-17; Lk 4.14-15.Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. 15 Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”
16 Mt 4.18-22; Lk 5.1-11; Jh 1.40-42.Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. 17 Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 18 Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
19 Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. 20 Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Jesu lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde
21 Mt 7.28-29; Lk 4.31-32.Lẹ́yìn náà, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapernaumu, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sínú Sinagọgu, ó sì ń kọ́ni. 22 Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn. 23 Lk 4.33-37.Ní àsìkò náà gan an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sinagọgu wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé, 24 Jh 6.69.“Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”
25 Jesu si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀.” 26 Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e ṣánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.
27 Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrín ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ tuntun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.” 28 Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè Galili.
Jesu mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá
29 Mt 8.14-15; Lk 4.38-39.Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu. 30 Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. 31 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
32 Mt 8.16-17; Lk 4.40-41.Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. 33 Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. 34 Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe.
Jesu ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láti gbàdúrà
35 Lk 4.42-43.Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. 36 Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. 37 Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
38 Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.” 39 Mt 4.23-25; Lk 4.44.Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.
Ọkùnrin tí o ní ààrùn ẹ̀tẹ̀
40 Mt 8.2-4; Lk 5.12-16.Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”
41 Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.” 42 Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.
43 Jesu sì kìlọ̀ fún un gidigidi 44 Le 13.49; 14.2-32.Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.” 45 Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jesu kò sì le wọ ìlú ní gbangba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní aginjù. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.

1:2 Mt 3.1-12; Lk 3.2-16; Jh 1.6,15,19-28.

1:2 Ml 3.1; Mt 11.10; Lk 7.27.

1:3 Isa 40.3.

1:4 Ap 13.24.

1:9 Mt 3.13-17; Lk 3.21-22; Jh 1.29-34.

1:11 Sm 2.7.

1:12 Mt 4.1-11; Lk 4.1-13.

1:14 Mt 4.12-17; Lk 4.14-15.

1:16 Mt 4.18-22; Lk 5.1-11; Jh 1.40-42.

1:21 Mt 7.28-29; Lk 4.31-32.

1:23 Lk 4.33-37.

1:24 Jh 6.69.

1:29 Mt 8.14-15; Lk 4.38-39.

1:32 Mt 8.16-17; Lk 4.40-41.

1:35 Lk 4.42-43.

1:39 Mt 4.23-25; Lk 4.44.

1:40 Mt 8.2-4; Lk 5.12-16.

1:44 Le 13.49; 14.2-32.