24
1 Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Olúwa lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù. 2 Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ 3 ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀,
“Àsọtẹ́lẹ̀ tí Balaamu ọmọ Beori,
àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,
4 àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ là kedere.
5 “Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu,
àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli!
6 “Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde,
gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,
gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,
gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.
7 Omi yóò sàn láti inú garawa:
èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
“Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ;
ìjọba wọn yóò di gbígbéga.
8 “Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá;
wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré.
Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run,
wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú;
wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.
9 Gẹ 49.9.Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,
bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?
“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,
kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”
10 Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. 11 Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.”
12 Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, 13 ‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’? 14 Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”
Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ẹ̀kẹrin Balaamu
15 Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe:
“Òwe Balaamu ọmọ Beori,
òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,
16 ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí,
tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo,
tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí:
17 “Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí.
Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́.
Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu;
yóò yọ jáde láti Israẹli.
Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu,
yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.
18 Wọn yóò borí Edomu;
yóò ṣẹ́gun Seiri ọ̀tá rẹ̀,
ṣùgbọ́n Israẹli yóò dàgbà nínú agbára.
19 Olórí yóò jáde láti Jakọbu
yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”
Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ìkẹyìn Balaamu
20 Nígbà náà ni Balaamu rí Amaleki ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe:
“Amaleki ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”
21 Nígbà náà ní ó rí ará Keni ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe:
“Ibùgbé rẹ ní ààbò,
ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta;
22 síbẹ̀ ẹ̀yin ará Keni ni yóò di píparun
nígbà tí Asiria bá mú yín ní ìgbèkùn.”
23 Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:
“Háà, ta ni ó lè yè nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?
24 Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdókọ̀ Kittimu;
wọn yóò ṣẹ́gun Asiria àti Eberi,
ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun.”
25 Nígbà náà ni Balaamu dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Balaki sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀.