Ìwé Saamu   
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ  
 1
Saamu 1–41  
 1  Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,  
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,  
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,  
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.   
 2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa  
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.   
 3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,  
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀  
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.  
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.   
 4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!  
Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà  
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.   
 5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,  
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.   
 6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,  
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.