Saamu 10
1 Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?
Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
2 Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
3 Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa.
4 Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.
5 Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6 O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí.
Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”
7 Ro 3.14.Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;
wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
8 Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò.
Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.
Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
9 Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;
Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;
ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
10 Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
11 Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”
12 Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.
Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
13 Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?
Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,
“Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
14 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;
Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.
Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
15 Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;
pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀
tí a kò le è rí.
16 Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé;
àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
17 Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;
Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
18 láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára,
kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé,
kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.