Saamu 81
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.
Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.
 
Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.
 
Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.
 
Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
mo dán an yín wò ní odò Meriba.
Sela.
 
“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.
 
11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.
 
13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé.
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”