Saamu 91
1 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,
“Òun ni ààbò àti odi mi,
Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.
3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú
ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,
àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;
òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,
tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
6 tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,
tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
7 Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ
àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.
9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́,
Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 Mt 4.6; Lk 4.10-11.Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 Lk 10.19.Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un.
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn,
èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”