Saamu 110
Ti Dafidi. Saamu.
1 Mt 22.44; 26.64; Mk 12.36; 14.62; 16.19; Lk 20.42-43; 22.69; Ap 2.34; 1Kọ 15.25; Ef 1.20; Kl 3.1; Hb 1.3,13; 10.12-13; 12.2.Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,
“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
2 Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
3 Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.
kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
5 Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
7 Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.
Saamu 110:1 Mt 22.44; 26.64; Mk 12.36; 14.62; 16.19; Lk 20.42-43; 22.69; Ap 2.34; 1Kọ 15.25; Ef 1.20; Kl 3.1; Hb 1.3,13; 10.12-13; 12.2.
Saamu 110:4 Hb 5.6,10; 6.20; 7.11,15,21.