10
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi sí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Israẹli ni kí wọ́n le ní ìgbàlà. Ro 9.31.Nítorí mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ wí pé, wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀. Ro 1.17.Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run. Ga 3.24; Ro 3.22; 7.1-4.Nítorí Kristi ni òpin òfin sí òdodo fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbà á gbọ́.
Le 18.5; Ne 9.29; El 20.11,13,21; Ro 7.10.Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” De 30.12-13; Ro 9.30.Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?’ ” (èyí ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀), “tàbí, ‘Ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?’ ” (èyí ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá). De 30.14.Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù pé: Mt 10.32; Lk 12.8; Ap 16.31.Bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. 10 Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. 11 Isa 28.16; Ro 9.33.Nítorí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” 12 Ro 3.22,29; Ga 3.28; Kl 3.11; Ap 10.36.Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. 13 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”
14 Ǹjẹ́ wọn ó ha ti ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o ha sì ti ṣe gbọ́ láìsí oníwàásù? 15 Isa 52.7.Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!”
16 Isa 53.1; Jh 12.38.Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?” 17 Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 18 Sm 19.4; Kl 1.6,23.Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́:
“Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀,
àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.”
19 De 32.21; Ro 11.11,14.Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé,
“Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú.
Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”
20 Isa 65.1; Ro 9.30.Ṣùgbọ́n Isaiah tilẹ̀ láyà, ó wí pé,
“Àwọn tí kò wá mi rí mi;
Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.”
21 Isa 65.2.Ṣùgbọ́n nípa ti Israẹli ni ó wí pé,
“Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi
sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”

10:2 Ro 9.31.

10:3 Ro 1.17.

10:4 Ga 3.24; Ro 3.22; 7.1-4.

10:5 Le 18.5; Ne 9.29; El 20.11,13,21; Ro 7.10.

10:6 De 30.12-13; Ro 9.30.

10:8 De 30.14.

10:9 Mt 10.32; Lk 12.8; Ap 16.31.

10:11 Isa 28.16; Ro 9.33.

10:12 Ro 3.22,29; Ga 3.28; Kl 3.11; Ap 10.36.

10:15 Isa 52.7.

10:16 Isa 53.1; Jh 12.38.

10:18 Sm 19.4; Kl 1.6,23.

10:19 De 32.21; Ro 11.11,14.

10:20 Isa 65.1; Ro 9.30.

10:21 Isa 65.2.