13
Ṣíṣe ìgbọ́ràn sí àwọn aláṣẹ
Tt 3.1; 1Pt 2.13-14; Òw 8.15; Jh 19.11.Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti lànà rẹ̀ wá. Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn. 1Pt 2.14.Nítorí àwọn ìjòyè kò wá láti dẹ́rùbà àwọn tí ń ṣe rere, bí kò ṣe àwọn tó ń ṣe búburú. Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ di òmìnira kúrò nínú ẹ̀rù ẹni tó wà ní ipò àṣẹ. Nítorí náà ṣe èyí tó ó dára, ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. 1Tẹ 4.6.Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni i ṣe fún ọ́ sí rere. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣé búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò gbé idà náà lásán. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní í ṣe, olùgbẹ̀san láti ṣiṣẹ́ ìbínú lára ẹni tí ń ṣe búburú. Nítorí náà, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ má tẹríba fún àwọn aláṣẹ, kì í ṣe nítorí ti ìbínú nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn pẹ̀lú.
Nítorí ìdí èyí, ẹ san owó òde pẹ̀lú, nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, èyí náà ni wọ́n ń bojútó nígbà gbogbo. Mt 22.21; Mk 12.17; Lk 20.25.Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó òde fún ẹni tí owó òde í ṣe tirẹ̀: owó bodè fún ẹni tí owó bodè í ṣe tirẹ̀: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù í ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá í ṣe tirẹ̀.
Ẹ jẹ gbèsè ìfẹ́
Mt 22.39-40; Ro 13.10; Ga 5.14; Kl 3.14; Jk 2.8.Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohun kan, bí kò ṣe pé kí a fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já. Ek 20.13-14; De 5.17-18; Le 19.18; Mt 19.19.Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.” 10 Mt 22.39-40; Ro 13.8; Ga 5.14; Jk 2.8.Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀, nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.
Ọjọ́ Olúwa fẹ́rẹ dé
11 Ef 5.14; 1Tẹ 5.6.Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun, nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. 12 1Jh 2.8; Ef 5.11; 1Tẹ 5.8.Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 13 1Tẹ 4.12; Ga 5.19-21.Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. 14 Ga 3.27; 5.16.Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.

13:1 Tt 3.1; 1Pt 2.13-14; Òw 8.15; Jh 19.11.

13:3 1Pt 2.14.

13:4 1Tẹ 4.6.

13:7 Mt 22.21; Mk 12.17; Lk 20.25.

13:8 Mt 22.39-40; Ro 13.10; Ga 5.14; Kl 3.14; Jk 2.8.

13:9 Ek 20.13-14; De 5.17-18; Le 19.18; Mt 19.19.

13:10 Mt 22.39-40; Ro 13.8; Ga 5.14; Jk 2.8.

13:11 Ef 5.14; 1Tẹ 5.6.

13:12 1Jh 2.8; Ef 5.11; 1Tẹ 5.8.

13:13 1Tẹ 4.12; Ga 5.19-21.

13:14 Ga 3.27; 5.16.