16
Ìkíni
Mo fi Febe arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díákónì nínú ìjọ tí ó wà ní Kenkerea. Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.
 
Ap 18.2.Ẹ kí Priskilla àti Akuila, àwọn tí ó ti jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jesu. Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í ṣe èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.
1Kọ 16.19.Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń péjọpọ̀ ní ilé wọn.
Ẹ kí Epenetu ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di ti Kristi ní orílẹ̀-èdè Asia.
Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ṣe làálàá púpọ̀ lórí wa.
Ẹ kí Androniku àti Junia, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrín àwọn aposteli, wọ́n sì ti wà nínú Kristi ṣáájú mi.
Ẹ kí Ampliatu, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa.
Ẹ kí Urbani, alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Kristi àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Staki.
10 Ẹ kí Apelle, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kristi.
Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Aristobulu.
11 Ẹ kí Herodioni, ìbátan mi.
Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Narkissu tí wọ́n wá nínú Olúwa.
12 Ẹ kí Trifena àti Trifosa, àwọn obìnrin tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.
Ẹ kí Persi ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.
13 Ẹ kí Rufusi, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀lú.
14 Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Hermesi àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn.
15 Ẹ kí Filologu, àti Julia, Nereu, àti arábìnrin rẹ̀, àti Olimpa, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn.
16  2Kọ 13.12; 1Tẹ 5.26; 1Pt 5.14.Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.
Gbogbo ìjọ Kristi kí yín.
 
17  Ga 1.8-9; 2Tẹ 3.6,14; 2Jh 10.Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. 18 Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà. 19  Ro 1.8; 1Kọ 14.20.Nítorí ìgbọ́ràn yín tànkálẹ̀ dé ibi gbogbo, nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.
 
20  1Kọ 16.23; 2Kọ 13.14; Ga 6.18; Fp 4.23; 1Tẹ 5.28; 2Tẹ 3.18; If 22.21.Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.
 
Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.
 
21  Ap 16.1.Timotiu alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lukiu, àti Jasoni, àti Sosipateru, àwọn ìbátan mi, kí yín.
22 Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa.
23  1Kọ 1.14.Gaiusi, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́.
Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́.* Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí ìkíni wọn ránṣẹ́. 24 Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.
 
25 Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, 26 ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́; 27 kí ògo wà fún Ọlọ́run, ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.

16:3 Ap 18.2.

16:5 1Kọ 16.19.

16:16 2Kọ 13.12; 1Tẹ 5.26; 1Pt 5.14.

16:17 Ga 1.8-9; 2Tẹ 3.6,14; 2Jh 10.

16:19 Ro 1.8; 1Kọ 14.20.

16:20 1Kọ 16.23; 2Kọ 13.14; Ga 6.18; Fp 4.23; 1Tẹ 5.28; 2Tẹ 3.18; If 22.21.

16:21 Ap 16.1.

16:23 1Kọ 1.14.

*16:23 Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí ìkíni wọn ránṣẹ́. 24 Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.