3
1 Ní orí ibùsùn mi ní òru
mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;
mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.
2 Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,
ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;
èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.
3 Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.
“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”
4 Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀
ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ
títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,
sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.
5 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú
kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè
kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
6 Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá
bí ọ̀wọ̀n èéfín
tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára
pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?
7 Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni,
àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,
àwọn akọni Israẹli,
8 gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,
gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,
idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,
wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru
9 Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;
o fi igi Lebanoni ṣe é.
10 Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀,
o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀.
Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,
inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí.
“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
11 Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni,
kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé,
adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e
ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,
ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.