8
Ọlọ́run ṣe ìpinnu láti bùkún Jerusalẹmu
Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá.
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Owú ńlá ńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńlá ńlá ni mo fi jowú fún un.”
Báyìí ni Olúwa wí, “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu. Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn. Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹmpili. 10 Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, owó ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
12 “Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀, àjàrà yóò ṣo èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí. 13 Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún, ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”
14 Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà. 15 “Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalẹmu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù. 16 Ef 4.25.Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. 17 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí.
18 Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.
19 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”
20 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀. 21 Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’ 22 Nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jerusalẹmu; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojúrere Olúwa.”
23 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dìímú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”

8:16 Ef 4.25.