28
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí ọba Tire
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: +“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi,
ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;
Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà,
ní àárín gbùngbùn Òkun.”
Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí?
Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?
Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ,
ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ,
àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà,
nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ,
ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
ọkàn rẹ gbé sókè,
nítorí ọrọ̀ rẹ.
“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,
pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ,
ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè;
wọn yóò yọ idà wọn sí ọ,
ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ,
wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò,
ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná,
àwọn tí a pa ní àárín Òkun.
Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”
ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?
Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,
ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.
10 Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà,
ní ọwọ́ àwọn àjèjì.
Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
 
11 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 12 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà,
o kún fún ọgbọ́n,
o sì pé ní ẹwà.
13 Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run;
onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ;
sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì,
àti jasperi, safire, emeradi,
turikuose, àti karbunkili, àti wúrà,
ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà,
láti ara wúrà,
ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
14 A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,
torí èyí ni mo fi yàn ọ́.
Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;
ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná.
15 Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ,
láti ọjọ́ tí a ti dá ọ,
títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
16 Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ,
ìwọ kún fún ìwà ipá;
ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀.
Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù,
bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.
Èmi sì pa ọ run,
ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.
17 Ọkàn rẹ gbéraga,
nítorí ẹwà rẹ.
Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,
nítorí dídára rẹ.
Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;
mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.
18 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,
ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.
Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,
láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,
èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,
lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
19 Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,
ní ẹnu ń yà sí ọ;
ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,
ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Sidoni
20  +Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 21 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i, 22 kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni,
a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ.
Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ,
tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ.
23 Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ,
èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ,
ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ,
pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.
24 “ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.
25 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu. 26 Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígbà tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”
+ 28:2 Da 11.36; 2Tẹ 2.4; If 13.5. + 28:20 Jl 3.4-8; Sk 9.2.