29
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Ejibiti
+Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti
ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí
àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ.
Èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;
èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ
èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ
gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,
àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù
ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:
ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko
a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.
Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó
àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.
Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa.
 
“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.
“ ‘Nítorí náà, èyí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.
“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili, Èmi ni mo ṣe é,” 10 nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11 Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12 Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.
13 “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí. 14 Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀. 15 Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. 16 Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”
Èrè Nebukadnessari
17 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18 “Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn. 19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀. 20 Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.
21 “Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”
+ 29:1 Isa 19; Jr 46; Sk 14.18-19.