8
Israẹli yípadà kúrò ní ọnà
“Fi ìpè sí ẹnu rẹ!
Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa
nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú,
wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
Israẹli kígbe pè mí,
‘Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’
Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀
ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀.
Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi
wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀.
Wọ́n fi fàdákà àti wúrà
ṣe ère fún ara wọn,
si ìparun ara wọn.
Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria!
Ìbínú mi ń ru sí wọn:
yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?
Israẹli ni wọ́n ti wá!
Ère yìí agbẹ́gilére ló ṣe é,
àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.
 
“Wọ́n gbin afẹ́fẹ́
wọ́n sì ká ìjì.
Igi ọkà kò lórí,
kò sì ní mú oúnjẹ wá.
Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà
àwọn àjèjì ni yóò jẹ.
A ti gbé Israẹli mì,
báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
bí ohun èlò tí kò wúlò.
Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri.
Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín Orílẹ̀-èdè,
Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí.
Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù
lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.
 
11 “Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀
gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn,
ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì.
13 Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi,
wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀,
ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.
Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Wọn yóò padà sí Ejibiti.
14  +Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀
Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀
Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀
ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan
sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”
+ 8:14 Am 1.4,7,10,12,14; 2.2,5.