9
Ìdájọ́ fún ẹsẹ̀ Israẹli 
 
1 Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli;  
má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.  
Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín.  
Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè  
ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.   
2 Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ  
wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀.   
3 Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa  
Efraimu yóò padà sí Ejibiti,  
yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.   
4 Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa.  
Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn.  
Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.  
Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́.  
Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn  
kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.   
   
 
5 Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn  
ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?   
6 Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun  
Ejibiti yóò kó wọn jọ,  
Memfisi yóò sì sin wọ́n.  
Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún,  
Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn.  
Ẹ̀gún yóò sì bo  
gbogbo àgọ́ wọn.   
7  Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀;  
àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé.  
Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí.  
Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀  
ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni.  
A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀,  
a ka ẹni ìmísí sí asínwín.   
8 Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,  
ni olùṣọ́ ọ Efraimu.  
Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀  
àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.   
9 Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́  
gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah  
Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn  
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.   
   
 
10 “Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù.  
Mo rí àwọn baba yín,  
bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀.  
Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ,  
wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni,  
ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́.  
11 Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ  
kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.   
12 Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà.  
Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn.  
Ègbé ni fún wọn,  
nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!   
13 Mo rí Efraimu bí ìlú Tire  
tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára  
ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn  
ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”   
   
 
14 Fún wọn, Olúwa!  
Kí ni ìwọ yóò fún wọn?  
Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́  
àti ọyàn gbígbẹ.   
   
 
15 “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali,  
Mo kórìíra wọn níbẹ̀,  
nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.  
Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi,  
Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́  
ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.   
16 Efraimu ti rẹ̀ dànù  
gbogbo rẹ̀ sì ti rọ,  
kò sì so èso.  
Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ.  
Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”   
   
 
17 Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀  
nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i;  
wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.