23
Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Tire
+Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire.
Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi!
Nítorí a ti pa Tire run
láìsí ilé tàbí èbúté.
Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni
ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.
 
Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù
àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni,
ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀.
Láti orí àwọn omi ńlá
ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá;
ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire,
òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè.
 
Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ
àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun,
nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀.
“Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí
Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin
tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”
Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti,
wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa
ìròyìn láti Tire.
 
Kọjá wá sí Tarṣiṣi;
pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,
ògbólógbòó ìlú náà,
èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ
láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
Ta ló gbèrò èyí sí Tire,
ìlú aládé,
àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé
tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká
ní orílẹ̀ ayé?
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,
láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba
àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá
ilé ayé sílẹ̀.
 
10 Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti,
ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi,
nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.
11  Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun
ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani
pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.
12 Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́,
ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí!
 
“Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi,
níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”
13 Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,
àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí.
Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di
ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;
wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,
wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò
wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.
 
14 Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!
15 Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:
16 “Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú,
ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;
lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin,
kí a lè ba à rántí rẹ.”
17  +Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé. 18 Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.
+ 23:1 El 26.1–28.19; Jl 3.4-8; Am 1.9-10; Sk 9.3-4. + 23:17 If 17.2.