24
Ìparun Olúwa lórí ilẹ̀ ayé
Kíyèsi i, Olúwa yóò sọ ohun
gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé
yóò sì pa á run
òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́
yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—
bákan náà ni yóò sì rí
fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn,
fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀,
fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin,
fún olùtà àti olùrà,
fún ayáni àti atọrọ
fún ayánilówó àti onígbèsè.
Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá
a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run.
Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
 
Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá,
ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un,
àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú
àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́;
wọ́n ti pa àwọn òfin run
wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà
wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.
Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;
àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.
Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,
àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,
gbogbo àwọn aláríyá sì kérora.
+Àríyá ti ṣaworo ti dákẹ́
ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró
ayọ̀ dùùrù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́
ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.
10 Ìlú tí a run ti dahoro,
ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.
11 Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì
gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́,
gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
12 Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,
ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú.
13 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé
àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi,
tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn
tí a kórè èso tán.
 
14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;
láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo
ọláńlá Olúwa.
15 Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;
gbé orúkọ Olúwa ga, àní
Ọlọ́run Israẹli,
ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun.
16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;
“Ògo ni fún olódodo n nì.”
Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé!
 
“Ègbé ni fún mi!
Alárékérekè dalẹ̀!
Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
17 Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́,
ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà
yóò ṣubú sínú ihò,
ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò
ni ìdẹ̀kùn yóò gbámú.
 
Ibodè ọ̀run ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.
19 Ilẹ̀ ayé ti fọ́
ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,
a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
20 Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,
ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;
ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù
tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.
 
21 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà
gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run
àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.
22 A ó sì kó wọn jọ pọ̀,
gẹ́gẹ́ bí ará túbú jọ sínú ihò,
a ó tì wọ́n mọ́ inú túbú,
a ó sì bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.
23 A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn;
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba
ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu,
àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.
+ 24:8 If 18.22.