25
Ẹ yin Olúwa
1 Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi;
èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì
fi ìyìn fún orúkọ rẹ
nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́
o ti ṣe ohun ńlá,
àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.
2 Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,
ìlú olódi ti di ààtàn,
ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;
a kì yóò tún un kọ́ mọ́.
3 Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò
bọ̀wọ̀ fún ọ;
àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú
yóò bu ọlá fún ọ.
4 Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì
ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀
ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì
bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.
Nítorí pé èémí àwọn ìkà
dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri
5 àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù.
O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,
gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.
6 Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
yóò ti pèsè
àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn
àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́
ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì
tí ó gbámúṣé.
7 Ní orí òkè yìí ni yóò pa
aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,
abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,
8 Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.
Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,
kúrò ní ojú gbogbo wọn,
Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò
ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
Olúwa ni ó ti sọ ọ́.
9 Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,
“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;
àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.
Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,
ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”
10 Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí
ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;
gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.
11 Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀
jáde láti lúwẹ̀ẹ́.
Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀
bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.
12 Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀
wọn yóò sì wà nílẹ̀,
Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,
àní sí erùpẹ̀ lásán.