18
Ní ilé amọ̀kòkò
1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe:
2 “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.”
3 Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́.
4 Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.
5 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
6 “Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.
7 Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun,
8 tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.
9 Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan.
10 Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.
11 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’
12 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”
13 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:
“Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè,
ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?
Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.
14 Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni
yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?
Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,
tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?
15 Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,
wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,
tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,
àti ọ̀nà wọn àtijọ́.
Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,
àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe.
16 Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di
nǹkan ẹ̀gàn títí láé,
gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,
wọn yóò sì mi orí wọn.
17 Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,
Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.
Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn
ní ọjọ́ àjálù wọn.”
18 Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.”
19 Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa,
gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.
20 Ṣe kí a fi rere san búburú?
Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi.
Rántí pé mo dúró níwájú rẹ,
mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn,
láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
21 Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn
jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà
jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó
jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn
kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
wọn lójú ogun.
22 Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn
nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun
kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́
kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ
gbogbo ète wọn láti pa mí,
má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ.
Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.