19
Èyí ní ohun tí Olúwa wí: “Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbàgbà ọkùnrin àti wòlíì. Kí o sì lọ sí àfonífojì ọmọ Beni-Hinnomu, níwájú ẹnu ibodè Harsiti, níbẹ̀ ni kí o sì kéde gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò sọ fún ọ. Kí o sì wí pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba àwọn Juda àti ẹ̀yin ará Jerusalẹmu. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya. Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjèjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí ọba Juda kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kún ilẹ̀ yìí. Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Baali láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sísun sí Baali—èyí tí èmi kò pàṣẹ láti ṣe, tí èmi kò sì sọ, tàbí tí kò sì ru sókè láti inú ọkàn mi. Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n àfonífojì Ìpakúpa.
“ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀. Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀. Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’
10 “Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ. 11 Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́. 12 Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti. 13 +Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
14 Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé, 15 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”
+ 19:13 Ap 7.42.