2
1 Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin Sioni  
pẹ̀lú àwọsánmọ̀ ìbínú rẹ̀!  
Ó sọ ògo Israẹli kalẹ̀,  
láti ọ̀run sí ayé;  
kò rántí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀  
ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.   
   
 
2 Láìní àánú ni Olúwa gbé  
ibùgbé Jakọbu mì;  
nínú ìrunú rẹ̀, ni ó wó  
ibi gíga ọmọbìnrin Juda lulẹ̀.  
Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ-aládé ọkùnrin  
lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀.   
   
 
3 Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké  
gbogbo ìwo Israẹli.  
Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò  
nígbà tí àwọn ọ̀tá dé.  
Ó run ní Jakọbu bí ọ̀wọ́-iná  
ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Sioni.   
   
 
4 Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá;  
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra.  
Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun  
ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná  
sórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni.   
   
 
5 Olúwa dàbí ọ̀tá;  
ó gbé Israẹli mì.  
Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì  
ó pa ibi gíga rẹ̀ run.  
Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀  
fún àwọn ọmọbìnrin Juda.   
   
 
6 Ó mú ìparun bá ibi mímọ́,  
ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run.  
Olúwa ti mú Sioni gbàgbé  
àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn;  
nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run  
ọba àti olórí àlùfáà.   
   
 
7 Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀  
ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀.  
Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́  
àwọn odi ààfin rẹ̀;  
wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwa  
gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn.   
   
 
8 Olúwa pinnu láti fa  
ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya.  
Ó gbé wọn sórí òsùwọ̀n,  
kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn.  
Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀  
wọ́n ṣòfò papọ̀.   
   
 
9 Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀;  
òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́.  
Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,  
kò sí òfin mọ́,  
àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí  
ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.   
   
 
10 Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni  
jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;  
wọ́n da eruku sí orí wọn  
wọ́n sì wọ aṣọ àkísà.  
Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu  
ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.   
   
 
11 Ojú mi kọ̀ láti sọkún,  
mo ń jẹ ìrora nínú mi,  
mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀  
nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,  
nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú  
ní òpópó ìlú.   
   
 
12 Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,  
“Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó  
bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe  
ní àwọn òpópónà ìlú,  
bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò  
láti ọwọ́ ìyá wọn.   
   
 
13 Kí ni mo le sọ fún ọ?  
Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,  
ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?  
Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,  
kí n lè tù ọ́ nínú,  
ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?  
Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.  
Ta ni yóò wò ọ́ sàn?   
   
 
14 Ìran àwọn wòlíì rẹ  
jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;  
wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn  
tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.  
Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ  
jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.   
   
 
15 Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ  
pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;  
wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn  
sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:  
“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè  
ní àṣepé ẹwà,  
ìdùnnú gbogbo ayé?”   
   
 
16 Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn  
gbòòrò sí ọ;  
wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke  
wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.  
Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;  
tí a sì wá láti rí.”   
   
 
17 Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;  
ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,  
tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.  
Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú,  
ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ,  
ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.   
   
 
18 Ọkàn àwọn ènìyàn  
kígbe jáde sí Olúwa.  
Odi ọmọbìnrin Sioni,  
jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò  
ní ọ̀sán àti òru;  
má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,  
ojú rẹ fún ìsinmi.   
   
 
19 Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́,  
bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀  
tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi  
níwájú Olúwa.  
Gbé ọwọ́ yín sókè sí i  
nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀  
tí ó ń kú lọ nítorí ebi  
ní gbogbo oríta òpópó.   
   
 
20 “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó.  
Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí.  
Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn,  
àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún?  
Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì  
ní ibi mímọ́ Olúwa?   
   
 
21 “Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀  
sínú eruku àwọn òpópó;  
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi  
ti ṣègbé nípa idà.  
Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ,  
Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.   
   
 
22 “Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè,  
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi.  
Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa  
kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè;  
àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn,  
ni ọ̀tá mi parun.”