3
Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú
pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn
nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀.
Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi
síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
 
Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó
ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká
pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn,
bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
 
Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ;
ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,
ó kọ àdúrà mi.
Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi;
ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.
 
10 Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀,
bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.
11 Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀
ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.
12 Ó fa ọfà rẹ̀ yọ
ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
 
13 Ó fa ọkàn mí ya
pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
14 Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi;
wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.
15 Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò
àti ìdààmú bí omi.
 
16 Ó ti fi òkúta kán eyín mi;
ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
17 Mo ti jìnnà sí àlàáfíà;
mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
18 Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ
àti ìrètí mi nínú Olúwa.”
 
19 Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,
ìkorò àti ìbànújẹ́.
20 Mo ṣèrántí wọn,
ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn
àti nítorí náà ní mo nírètí.
 
22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,
nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;
títóbi ni òdodo rẹ̀.
24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;
nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
 
25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,
sí àwọn tí ó ń wá a.
26 Ó dára kí a ní sùúrù
fún ìgbàlà Olúwa.
27 Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà
nígbà tí ó wà ní èwe.
 
28 Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́,
nítorí Olúwa ti fi fún un.
29 Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku—
ìrètí sì lè wà.
30 Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,
sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
 
31 Ènìyàn kò di ìtanù
lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
32 Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,
nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
33 Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá
tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
 
34 Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀
gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.
35 Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀
níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,
36 láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà,
ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.
 
37 Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀
tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.
38 Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ
ni rere àti búburú tí ń wá?
39 Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn
nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?
 
40 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò,
kí a sì tọ Olúwa lọ.
41 Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè
sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,
42 “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀
ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.
 
43 “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa;
ìwọ ń parun láìsí àánú.
44 Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ
pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
45 Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn
láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.
 
46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn
gbòòrò sí wa.
47 Àwa ti jìyà àti ìparun,
nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
48 Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò
nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.
 
49 Ojú mi kò dá fún omijé,
láì sinmi,
50 títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀
láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
51 Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi
nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.
 
52 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí
dẹ mí bí ẹyẹ.
53 Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò
wọ́n sì ju òkúta lù mí.
54 Orí mi kún fún omi,
mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.
 
55 Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa,
láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56 Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ
sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
57 O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,
o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”
 
58  Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,
o ra ẹ̀mí mi padà.
59 O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi.
Gba ẹjọ́ mi ró!
60 Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn,
gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.
 
61  Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn
àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,
62 ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ
sí mi ní gbogbo ọjọ́.
63 Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde,
wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.
 
64  Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn
fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
65 Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn,
kí o sì fi wọ́n ré.
66 Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú,
lábẹ́ ọ̀run Olúwa.