5
Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa;
wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.
Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò,
ilé wa ti di ti àjèjì.
Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,
àwọn ìyá wa ti di opó.
A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;
igi wa di títà fún wa.
Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa;
àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.
Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria
láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.
Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́,
àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa,
kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.
Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa
nítorí idà tí ó wà ní aginjù.
10 Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò,
ebi sì yó wa bí àárẹ̀.
11 Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni,
àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.
12 Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn;
kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.
13 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta;
àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.
14 Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú;
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn.
15 Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;
ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
16 Adé ti ṣí kúrò ní orí wa
ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.
17 Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,
nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.
18 Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro
lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.
 
19 Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé;
ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.
20 Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?
Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?
21 Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà;
mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì,
22 àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá
tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.