Àwọn òwe Solomoni
10
Àwọn òwe Solomoni.
Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn,
ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.
 
Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè,
ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
 
Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo,
ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
 
Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà,
ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀.
 
Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.
 
Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo,
ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.
 
Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún,
ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.
 
Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ,
ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.
 
Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu,
ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.
 
10 Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn,
aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.
 
11 Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,
ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.
 
12 Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.
 
13 Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye,
ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.
 
14 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ,
ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.
 
15 Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn,
ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.
 
16 Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn,
ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.
 
17 Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.
 
18 Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́
ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.
 
19 Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù
ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
 
20 Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà,
ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí.
 
21 Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀,
ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.
 
22 Ìbùkún Olúwa ń mú ọrọ̀ wá,
kì í sì í fi ìdààmú sí i.
 
23 Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú,
ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.
 
24 Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;
olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.
 
25 Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,
ṣùgbọ́n olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.
 
26 Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú,
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.
 
27 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,
ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.
 
28 Ìrètí olódodo ni ayọ̀,
ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.
 
29 Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo,
ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.
 
30 A kì yóò fa olódodo tu láéláé,
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
 
31 Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,
ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.
 
32 Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà,
ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.