9
Ìpè ti ọgbọ́n àti àìgbọ́n
Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,
ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.
Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,
láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
“Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”
Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé,
“Wá, ẹ wá jẹ́ oúnjẹ mi
sì mu wáìnì tí mo ti pò.
Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;
rìn ní ọ̀nà òye.
 
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù
ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.
Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i
kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.
 
10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,
ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.
11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:
bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
 
13 Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;
ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.
14 Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀
lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,
15 ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ,
tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
16 “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!”
Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
17 “Omi tí a jí mu dùn
oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
18 Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀,
pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.