26
Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè
ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.
Bí ológoṣẹ́ tí ń ṣí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rábàbà
èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè
èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.
Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.
Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀
àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.
Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀
àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.
Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá
ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè.
Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro
ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè.
Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa
ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá.
Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí
ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.
10 Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan
ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.
11 +Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
12 Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?
Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.
 
13 Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà
kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”
14 Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.
15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ,
ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
16 Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,
ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.
 
17 Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú
ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.
 
18 Bí i asínwín ti ń ju
ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni
19 ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ
tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”
 
20 Láìsí igi, iná yóò kú
láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.
21 Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,
bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.
22 Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè
wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
 
23 Ètè jíjóni, àti àyà búburú,
dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò.
24 Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀
ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.
25 Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́
nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.
26 Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn
ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.
27 Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.
Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.
28 Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà,
ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.
 
+ 26:11 2Pt 2.22.