27
1 Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la  
nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.   
   
 
2 Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ,  
àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀.   
   
 
3 Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo  
ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.   
   
 
4 Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀  
ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?   
   
 
5 Ìbániwí gbangba sàn  
ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.   
   
 
6 Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́,  
ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.   
   
 
7 Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó  
ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.   
   
 
8 Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀  
ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.   
   
 
9 Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn  
bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.   
   
 
10 Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,  
má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ  
ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.   
   
 
11 Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi  
nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.   
   
 
12 Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́  
ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.   
   
 
13 Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì  
fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.   
   
 
14 Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀  
a ó kà á sí bí èpè.   
   
 
15 Àyà tí ó máa ń jà dàbí  
ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;   
16 dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun  
tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.   
   
 
17 Bí irin tí ń pọ́n irin mú  
bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.   
   
 
18 Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀  
ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.   
   
 
19 Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó  
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.   
   
 
20 Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí  
bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.   
   
 
21 Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà,  
ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.   
   
 
22 Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó,  
fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́  
ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.   
   
 
23 Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà  
bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;   
24 nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí  
adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.   
   
 
25 Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé   
26 àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ,  
àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.   
   
 
27 Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́  
láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ  
àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.