Ìwé Saamu
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
1
Saamu 1–41
1 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.