Saamu 2
1 Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
2 Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.
3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipò
lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”
7 Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:
Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
lónìí, èmi ti di baba rẹ.
8 Béèrè lọ́wọ́ mi,
Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”
10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù
ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.