Saamu 108
Orin. Saamu ti Dafidi.
+Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin
èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.
Jí ohun èlò orin àti haapu!
Èmi ó jí ní kùtùkùtù,
èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn.
Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ
ju àwọn ọ̀run lọ
àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀.
Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,
àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.
 
+Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;
fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,
kí o sì dá mi lóhùn
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé,
“Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,
èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò.
Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,
Efraimu ni ìbòrí mi,
Juda ni olófin mi,
Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,
lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”
 
10 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?
Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
11 Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀.
Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
12 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú,
nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.
13 Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin
nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
+ Saamu 108:1 Sm 57.7-11. + Saamu 108:6 Sm 60.5-12.