Saamu 109
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún,
má ṣe dákẹ́,
nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn
ti ya ẹnu wọn sí mi
wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi.
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;
wọ́n bá mi jà láìnídìí
Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,
ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi
àti ìríra fún ìfẹ́ mi.
 
Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ
jẹ́ kí àwọn olùfisùn
dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́
kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀.
+Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú;
kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀.
Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba
kí aya rẹ̀ sì di opó.
10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri
kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn.
11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní
jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un
tàbí kí wọn káàánú lórí
àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba.
13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò
kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀.
14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí
ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa.
Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò.
15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa
kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
 
16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,
ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,
kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:
bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.
18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù
bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi.
19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara,
àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo.
20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá;
àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.
 
21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè,
ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ.
Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí.
22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,
àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,
mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà
ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
25 +Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;
nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.
 
26 Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;
gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí
wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.
28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre,
nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,
ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀.
29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú
kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.
 
30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi
ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín.
31 Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìní
láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.
+ Saamu 109:8 Ap 1.20. + Saamu 109:25 Mt 27.39; Mk 15.29.