Saamu 113
Ẹ máa yin Olúwa.
 
Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa.
Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.
 
Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
tí ó gbé ní ibi gíga.
Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
 
Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀,
àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.
 
Ẹ yin Olúwa.