Saamu 114
Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
Juda wà ní ibi mímọ́,
Israẹli wà ní ìjọba.
 
+Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
Jordani sì padà sẹ́yìn.
Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
 
Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
 
Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
tí ó sọ àpáta di adágún omi,
àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
+ Saamu 114:3 El 14.21; Jo 3.16.