Saamu 119
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,
ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa.
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́
tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;
wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀
kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin
láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
Nígbà náà, ojú kò ní tì mí
nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin
bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀,
má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.
 
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi
kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ.
12 Ìyìn ni fún Olúwa;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò
gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
14 Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,
bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ
èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ.
16 Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;
èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.
 
17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;
èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
18 La ojú mi kí èmi lè ríran rí
ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé,
má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà
nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún
tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,
nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀,
wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,
ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi;
àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.
 
25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa
má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
 
33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí òfin rẹ dára.
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
 
41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ.
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
ojú kì yóò sì tì mí,
47 nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
 
49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa,
èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
níbikíbi tí èmi ń gbé.
55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa,
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
56 nítorí tí mo
gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
 
57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:
èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
nítorí òfin òdodo rẹ.
63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, Olúwa,
kọ́ mi ní òfin rẹ.
 
65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ
gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,
nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,
ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,
èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,
ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú
nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ
ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
 
73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
75 Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
 
81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé;
ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
 
89 Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni;
ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run.
90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91 Òfin rẹ dúró di òní
nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́.
94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
 
97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
 
105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi
àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.
106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn
wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
107 A pọ́n mi lójú gidigidi;
Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
108  Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,
kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,
ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;
àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́
láé dé òpin.
 
113 Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì,
ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;
èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,
kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ,
kí èmi kí ó lè yè
Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;
nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́;
nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀:
èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.
 
121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:
má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:
má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,
fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ
kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye
kí èmi lè ní òye òfin rẹ
126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;
nítorí òfin rẹ ti fọ́.
127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ
ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
128 nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,
èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.
 
129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
 
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin.
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi.
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
fún mi ní òye kí èmi lè yè.
 
145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
dá mi lóhùn Olúwa,
èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;
èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,
nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:
pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,
ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,
àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ
tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.
 
153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,
nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;
pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú
nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa;
pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,
ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́
nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;
pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;
gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
 
161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,
ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ
bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe
ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́
nítorí òfin òdodo rẹ.
165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,
kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa,
èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,
nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀.
168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,
nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
 
169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;
fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,
àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù.
Wá ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.