Saamu 120
Orin fún ìgòkè.
Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,
ó sì dá mi lóhùn.
Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké
àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
 
Kí ni kí a fi fún ọ?
Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,
pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.
 
Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,
nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!
Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé
láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
Ènìyàn àlàáfíà ni mí;
ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.