Saamu 121
Orin fún ìgòkè.
Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?
Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá,
ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
 
Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.
 
Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.
 
Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
yóò pa ọkàn rẹ mọ́
Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.