Saamu 122
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,
“Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.”
Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
ìwọ Jerusalẹmu.
 
Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan.
Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
àwọn ẹ̀yà Olúwa,
ẹ̀rí fún Israẹli,
láti máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.
 
Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀.
Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,
èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.