Saamu 37
Ti Dafidi.
Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,
kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,
wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.
 
Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;
torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
Ṣe inú dídùn sí Olúwa;
òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
 
Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;
gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
 
Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,
kí o sì fi sùúrù dúró dè é;
má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,
nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
 
Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,
má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
 
10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;
nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
 
12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
 
14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
 
16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.
 
18  Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé.
19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
 
20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;
wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
 
21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
22 nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
 
23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
24 bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,
nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.
 
25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;
síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,
tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
a sì máa bùsi i fún ni.
 
27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
28 Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
 
Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
 
30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;
àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
 
32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,
Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33  Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,
nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
 
34 Dúró de Olúwa,
kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.
Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;
nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
 
35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,
ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;
bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.
 
37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;
nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;
ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.
 
39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40  Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;
yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,
nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.