Saamu 58
Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.
Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́
ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́
ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,
ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.
 
Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,
lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.
Oró wọn dàbí oró ejò,
wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,
tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,
bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
 
Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;
ní ẹnu wọn,
ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.
Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;
nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé
bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.
 
Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;
bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,
nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé,
“Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;
lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”