Saamu 57
Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.
Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.
 
Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.
 
Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.
 
Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.
 
Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:
a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,
wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:
ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.
 
+Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;
ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
Jí, ìwọ ọkàn mi!
Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!
Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.
 
Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;
òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.
 
11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;
kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.
+ Saamu 57:7 Sm 108.1-5.