Saamu 63
Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.
Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
níbi tí kò sí omi.
 
Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
mo rí agbára àti ògo rẹ.
Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
ètè mi yóò fògo fún ọ.
Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.
 
Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
Ọkàn mí fà sí ọ:
ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
 
Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;
wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú
wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.
 
11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run
ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo
ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.