Saamu 64
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi
pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.
 
Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.
 
Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
“A wa ti parí èrò tí a gbà tán!”
Lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.
 
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;
wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,
gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù
wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run
wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.
 
10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa
yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.
Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.