Saamu 79
Saamu ti Asafu.
Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;
wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,
wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.
Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ
fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,
ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi
yí Jerusalẹmu ká,
kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,
àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.
 
Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?
Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?
Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè
tí kò ní ìmọ̀ rẹ,
lórí àwọn ìjọba
tí kò pe orúkọ rẹ;
nítorí wọ́n ti run Jakọbu
wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
 
Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn
jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,
nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
fún ògo orúkọ rẹ;
gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì
nítorí orúkọ rẹ.
10 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé,
“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”
 
Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.
11 Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ,
gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ
ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.
12 San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje
nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa.
13 Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ,
àti àgùntàn pápá rẹ,
yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;
láti ìran dé ìran
ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.