Saamu 80
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì Ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.
Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran.
Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù,
tàn jáde níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.
 
Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí a bá à lè gbà wá là.
 
Olúwa Ọlọ́run alágbára,
ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
 
Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
kí a ba à lè gbà wá là.
 
Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;
ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,
ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀
ó sì kún ilẹ̀ náà.
10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,
ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
 
12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀
tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́
àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!
Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15 gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,
àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
 
16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;
ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
 
19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;
kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí á ba à lè gbà wá là.