5
Olùfẹ́  
1 Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;  
mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.  
Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;  
mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.  
Ọ̀rẹ́  
Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,  
àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.   
Olólùfẹ́  
2 Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.  
Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.  
“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,  
àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi,  
orí mi kún fún omi ìrì,  
irun mi kún fún òtútù òru.”   
3 Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi  
ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?  
Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi  
ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?   
4 Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn  
inú mi sì yọ́ sí i.   
5 Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,  
òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,  
òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn  
sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn.   
6 Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,  
ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ  
ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.  
Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.  
Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn.   
7 Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi  
bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.  
Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;  
wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.  
Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!   
8 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín  
bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,  
kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?  
Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.   
Ọ̀rẹ́  
9 Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ,  
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?  
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ  
tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?   
Olólùfẹ́  
10 Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n  
ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lọ.   
11 Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ  
ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ  
ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò.   
12 Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà  
ní ẹ̀bá odò tí ń sàn,  
tí a fi wàrà wẹ̀,  
tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́.   
13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí  
tí ó sun òórùn tùràrí dídùn  
Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì  
ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn.   
14 Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,  
tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká.  
Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán  
tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.   
15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mabu  
tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára.  
Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni,  
tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.   
16 Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀  
ó wu ni pátápátá.  
Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu.  
Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.