6
Ọ̀rẹ́
Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,
kí a lè bá ọ wá a?
Olólùfẹ́
Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,
sí ibi ibùsùn tùràrí,
láti máa jẹ nínú ọgbà
láti kó ìtànná lílì jọ.
Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,
Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.
Olùfẹ́
Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa,
ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu,
ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.
Yí ojú rẹ kúrò lára mi;
nítorí ojú rẹ borí mi.
Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́
tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.
Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,
tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,
gbogbo wọn bí ìbejì,
kò sì ṣí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ,
rí bí ẹ̀là èso pomegiranate.
Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,
àti ọgọ́rin àlè,
àti àwọn wúńdíá láìníye.
Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,
ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀,
ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.
Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún
àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un.
Ọ̀rẹ́
10 Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,
tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn,
tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?
Olùfẹ́
11 Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi
láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì,
láti rí i bí àjàrà rúwé,
tàbí bí pomegiranate ti rudi.
12 Kí èmi tó mọ̀,
àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi.
Ọ̀rẹ́
13 Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulamati;
padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò.
Olùfẹ́
Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò,
bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu?